2 Chronicles 33:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí àwọn ọmọ Israẹli bá pa òfin mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati ìdájọ́ mi tí mo fún wọn láti ọwọ́ Mose, n kò ní ṣí wọn nídìí mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo ti yàn fún àwọn baba wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ilẹ̀ tí a yàn fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ fún wọn. Nípa gbogbo àwọn òfin, àsẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín ní pasẹ̀ Mósè.”