2 Chronicles 34:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sanwó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń mọlé, láti ra òkúta gbígbẹ́ ati pákó ati igi, kí wọ́n fi tún àwọn ilé tí àwọn ọba Juda ti sọ di àlàpà kọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn ọlọ́nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Júdà ti gbà láti tẹ́ ilé tí wọ́n ti bàjẹ́.