2 Chronicles 34:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà fi òtítọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣàkóso wọn ni: Jahati ati Ọbadaya, láti inú ìran Merari, ati Sakaraya ati Meṣulamu, láti inú ìran Kohati. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n mọ̀ nípa ohun èlò orin
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́ lórí wọn, láti darí wọn ní Jáhátì àti Obadíà, àwọn ọmọ Léfì láti Mérárì, àti Sekaríà àti Mèsúlámù, sọ̀kalẹ̀ láti Kónátì àwọn ọmọ Léfì gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.