2 Chronicles 34:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ tọ Ọlọrun lọ fún èmi ati àwọn eniyan tí wọ́n kù ní Juda ati ní Israẹli, ẹ ṣe ìwádìí ohun tí a kọ sinu ìwé náà; nítorí pé àwọn baba ńlá wa tàpá sí ọ̀rọ̀ OLUWA, wọn kò sì ṣe ohun tí a kọ sinu ìwé yìí ni OLUWA ṣe bínú sí wa lọpọlọpọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ lọ, ẹ bere lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn ti o kù ni Israeli ati ni Juda, niti ọ̀rọ iwe ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti a tú jade sori wa, nítori awọn bàba wa kò pa ọ̀rọ Oluwa mọ́, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu iwe yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ lọ kí ẹ lọ bérè lọ́wọ́ OLÚWA fún mi fún àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti Júdà nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú OLÚWA tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ OLÚWA mọ́, wọn kò sì tíì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”