2 Chronicles 34:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, Hilikaya ati àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e, lọ sọ́dọ̀ Hulida, wolii obinrin, iyawo Ṣalumu, ọmọ Tokihati, ọmọ Hasira tí ó jẹ́ alabojuto ibi tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí ní ìhà keji Jerusalẹmu tí Hulida ń gbé. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Hilkiah, ati awọn ti ọba ti yàn tọ̀ Hulda, woli obinrin, lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikehati, ọmọ Hasra, olutọju aṣọ (njẹ, o ngbe Jerusalemu, niha keji;) nwọn si ba a sọ̀rọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Híkíánì àti àwọn ènìyàn tí a yàn sì lọ láti sọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì Húlídà aya Ṣálúmù ọmọ Tókátì, ọmọ Hásíràh, olùtọ́jú ibi ìkásọsí, ó sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ní ìhà kejì.