2 Chronicles 34:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti sun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina li a o ṣe tú ibinu mi sori ihinyi, a kì yio si paná rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’