2 Chronicles 34:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ si isa-okú rẹ li alafia, bẹ̃ni oju rẹ kì yio ri gbogbo ibi ti emi o mu wá si ihinyi, ati sori awọn ti ngbe ibẹ. Bẹ̃ni nwọn mu èsi pada fun ọba wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsinyìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibíyìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.