2 Chronicles 34:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kẹjọ tí Josaya gorí oyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọde ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọrun Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Ní ọdún kejila, ó bẹ̀rẹ̀ sí wó àwọn pẹpẹ oriṣa ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati Jerusalẹmu. Ó wó àwọn òpó oriṣa Aṣera, ó sì fọ́ àwọn ère gbígbẹ́ ati èyí tí wọ́n rọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀, nigbati o si wà li ọdọmọde sibẹ, o bẹ̀rẹ si iwá Ọlọrun Dafidi, baba rẹ̀; ati li ọdun kejila, o bẹ̀rẹ si iwẹ̀ Juda ati Jerusalemu mọ́ kuro ninu ibi giga wọnni, ati ere-oriṣa, ati ere yiyá, ati ere didà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹ́jọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí íwá ojú Ọlọ́run Baba Dáfídì. Ní ọdún kéjìlá (12). Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ Júdà àti Jérúsálẹ́mù mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà, àti ère yíyá àti ère dídà.