2 Chronicles 34:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá lọ sí ilé OLUWA pẹlu gbogbo ará Juda, ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu; ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan yòókù; ati olówó ati talaka. Ọba ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo ọkunrin Juda, ati awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo enia ati ẹni-nla ati ẹni-kekere: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì lọ sókè ní ilé OLÚWA pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì gbogbo ènìyàn lati ẹní ńlá sí ẹní kékeré, ó sì kà á ní etí wọn gbogbo ọ̀rọ̀ ínú ìwé májẹ̀mú, tí wọ́n ti rí nínú ilé OLÚWA.