2 Chronicles 34:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó dúró ní ààyè rẹ̀, ó sì bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa fi tọkàntọkàn rìn ní ọ̀nà OLUWA, òun óo máa pa òfin rẹ̀ mọ́, òun óo máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, òun ó sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ó ní òun ó máa fi tọkàntọkàn pa majẹmu tí a kọ sinu ìwé náà mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si duro ni ipò rẹ̀, o si dá majẹmu niwaju Oluwa lati ma fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati ṣe ọ̀rọ majẹmu na ti a kọ sinu iwe yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú OLÚWA láti tẹ̀lé OLÚWA àti láti pa ofin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí ínú ìwé yìí.