2 Chronicles 34:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josaya run gbogbo àwọn ère oriṣa tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA Ọlọrun wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, wọn kò yipada kúrò lẹ́yìn OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josiah si kó gbogbo ohun-irira kuro ninu gbogbo ilu ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, o si mu ki gbogbo awọn ti o wà ni Israeli ki o sìn, ani ki nwọn sìn Oluwa Ọlọrun wọn. Ati li ọjọ rẹ̀ gbogbo nwọn kò yà kuro lati ma tọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn, lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósíà sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì sin OLÚWA Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.