2 Chronicles 34:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya, lẹ́yìn tí ó ti pa ìbọ̀rìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà, ó rán Ṣafani ọmọ Asalaya láti tún ilé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ ṣe pẹlu Maaseaya, gomina ìlú, ati Joa, ọmọ Joahasi tí ó jẹ́ alákòóso ìwé ìrántí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ li ọdun kejidilogun ijọba rẹ̀, nigbati o ti wẹ̀ ilẹ na mọ́, ati ile na, o rán Ṣafani, ọmọ Asaliah, ati Maaseiah, olori ilu na, ati Joa, ọmọ Joahasi, akọwe iranti, lati tun ile Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jósíà ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé OLÚWA, ó sì rán Ṣáfánì ọmọ Ásálíà àti Màséíà olórí ìlú náà, pẹ̀lú Jóà, ọmọ Jóáhásì, akọ̀wé, láti tún ilé OLÚWA Ọlọ́run ṣe.