2 Chronicles 34:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Hilikaya, olórí alufaa, wọ́n kó owó tí àwọn eniyan mú wá sí ilé OLUWA fún un, tí àwọn Lefi tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Manase, ati Efuraimu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń gbé Juda, Bẹnjamini ati Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si de ọdọ Hilkiah, olori alufa, nwọn fi owo na ti a mu wá sinu ile Ọlọrun le e lọwọ, ti awọn ọmọ Lefi, ti o ntọju ilẹkun, ti kójọ lati ọwọ Manasse ati Efraimu, ati lati ọdọ gbogbo awọn iyokù Israeli, ati lati gbogbo Juda ati Benjamini: nwọn si pada si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, ó sì fún-un ní owó náà tí ó mú wá sí ínú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Léfì ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́-ẹnú-ọ̀nà-ìbòdè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Ménásè Éfíráímù àti láti ọ̀dọ̀ Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì wọ́n sì padà sí Jérúsálẹ́mù.