2 Chronicles 35:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá, àwọn alufaa wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára àwọn ẹran náà sórí pẹpẹ, àwọn ọmọ Lefi sì bó awọ àwọn ẹran náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Léfì sì bo ẹranko.