2 Chronicles 35:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ́jú tiwọn ati ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni. Nítorí iṣẹ́ ṣíṣe kò jẹ́ kí àwọn alufaa rí ààyè, láti àárọ̀ títí di alẹ́. Wọ́n ń rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ń sun ọ̀rá ẹran níná. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi fi tọ́jú tiwọn, tí wọ́n sì tọ́jú ti àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin na nwọn mura silẹ fun ara wọn, ati fun awọn alufa; nitoriti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, wà ni riru ẹbọ sisun ati ọ̀ra titi di alẹ; nitorina awọn ọmọ Lefi mura silẹ fun ara wọn ati fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Árónì, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àsálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Árónì àlùfáà.