2 Chronicles 35:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Asafu dúró ní ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dafidi. Bẹ́ẹ̀ náà ni Asafu, Hemani, ati Jedutuni, aríran ọba. Àwọn aṣọ́nà tẹmpili kò kúrò ní ààyè wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ti tọ́jú ẹbọ ìrékọjá tiwọn fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Ásáfù, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dáfídì, Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì àwọn aríran ọba àti àwọn olùsọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ti múra sílẹ̀ fún wọn.