2 Chronicles 35:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò tíì sí irú àsè Àjọ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti ìgbà ayé wolii Samuẹli. Kò sì tíì sí ọba kankan ní Israẹli tí ó tíì ṣe àsè Àjọ Ìrékọjá bí Josaya ti ṣe pẹlu àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn eniyan Juda, àwọn tí wọ́n wá láti Israẹli ati àwọn ará Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si si irekọja kan ti o dabi rẹ̀ ti a ṣe ni Israeli lati igba ọjọ Samueli woli; bẹ̃ni gbogbo awọn ọba Israeli kò pa iru irekọja bẹ̃ mọ́, bi eyi ti Josiah ṣe, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Juda ati Israeli ti a ri nibẹ, ati awọn ti ngbe Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àjọ ìrékọjá náà kòsì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Ísírẹ́lì títí dé ọjọ́ wòlíì Sámúẹ́lì, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jósíà ti se, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo àwọn Júdà àti Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù.