2 Chronicles 35:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Jósíà ti tún ilẹ̀ náà se tán, Nékò ọba Éjíbítì gòkè lọ láti bá Keríkemísì jà lórí odo Éúfírátè, Jósíà sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.