2 Chronicles 35:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Josiah kò yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ rẹ̀, ṣugbọn o pa aṣọ ara rẹ dà, ki o le ba a jà, kò si fi eti si ọ̀rọ Neko lati ẹnu Ọlọrun wá, o si wá ijagun li àfonifoji Megiddo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósíà, bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tí kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le báa jà, kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó lọ láti jà lórí àfonífojì Mégídò.