2 Chronicles 35:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn tafatafa si ta Josiah, ọba: ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ gbé mi kuro; nitoriti mo gbà ọgbẹ gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Jósíà, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹgbé mi kúrò, èmi sì ti gba ọgbẹ́ gidigidi.”