2 Chronicles 35:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Júdà àti gbogbo Jérúsálẹ́mù sì sọ̀fọ̀ fún un.