2 Chronicles 35:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeremiah si pohùn rere ẹkún fun Josiah, ati gbogbo awọn akọrin ọkunrin, ati awọn akọrin obinrin, si nsọ ti Josiah ninu orin-ẹkún wọn titi di oni yi, nwọn si sọ wọn di àṣa kan ni Israeli; si kiyesi i, a kọ wọn ninu awọn orin-ẹkún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jeremáyà sì pohùn réré ẹkún fún Jósíà, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Jósíà nínú orin ẹkún wọn títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jérúsálẹ́mù, a sì kọọ́ sínú àwọn orin ẹkún.