2 Chronicles 35:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún àwọn ọmọ Léfì, ẹni tí ó sọ fún gbogbo àwọn Ísírẹ́lì ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún OLÚWA pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé OLÚWA tí Sólómónì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsìn yìí ẹ sin OLÚWA Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.