2 Chronicles 35:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Sólómónì.