2 Chronicles 35:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn olóyè náà fi tọkàntọkàn fún àwọn eniyan, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní nǹkan. Hilikaya, Sakaraya ati Jehieli, àwọn alákòóso ninu ilé Ọlọrun, fún àwọn alufaa ní ẹgbẹtala (2,600) ọ̀dọ́ aguntan ati ọmọ ewúrẹ́ ati ọọdunrun (300) mààlúù fún ẹbọ Ìrékọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn Àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Hílíkíyà, Sekaríà àti Jéhíélì, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún ẹran ọ̀sìn (300).