2 Chronicles 35:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi: Konanaya pẹlu Ṣemaaya ati Netaneli, àwọn arakunrin rẹ̀; ati Haṣabaya, Jeieli, ati Josabadi, àwọn olóyè ninu ọmọ Lefi dá ẹẹdẹgbaata (5,000) ọ̀dọ́ aguntan, ati ọmọ ewúrẹ́, ati ẹẹdẹgbẹta (500) mààlúù fún àwọn ọmọ Lefi kí wọn fi rú ẹbọ Ìrékọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti pẹ̀lú Koníà àti pẹ̀lú Ṣémíà àti Nàtaníẹ́lì, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabíà, Jélíélì àti Joábádì olórí àwọn ọmọ Léfì, ó sì pèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹbọ ìrékọjá (500) àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Léfì.