2 Chronicles 36:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ọdún yípo, Nebukadinesari, ọba Babiloni ranṣẹ lọ mú un wá sí Babiloni pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó sì fi Sedekaya, arakunrin rẹ̀ jọba ní Jerusalẹmu ati Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àmọ́dún, ọba Nebukadínsárì ránsẹ́ síi ó sì mú-un wá sí Bábílónì, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé OLÚWA, ó sì mú arákùnrin Jehóíákínì, Sedekíà, jọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.