2 Chronicles 36:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadinésárì pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ẹni tí ọrùn rẹ̀ wàkì, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.