2 Chronicles 36:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, nwọn si kẹgan ọ̀rọ rẹ̀, nwọn si fi awọn woli rẹ̀ ṣẹsin, titi ibinu Oluwa fi ru si awọn enia rẹ̀, ti kò fi si atunṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìransẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ sẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run ṣe ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì sí àtúnṣe.