2 Chronicles 36:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun mú kí ọba Kalidea gbógun tì wọ́n. Ọba náà fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Juda ninu tẹmpili, kò ṣàánú àwọn ọdọmọkunrin tabi wundia, tabi àwọn àgbà tabi arúgbó; gbogbo wọn ni Ọlọrun fi lé e lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Bábílónì tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdé bìnrin, wúndíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadinésárì lọ́wọ́.