2 Chronicles 36:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nebukadinesari kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù tí wọn kò pa lẹ́rú, ati àwọn ọmọ wọn. Ó kó wọn lọ sí Babiloni, wọ́n sì ń sin òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ títí di àkókò ìjọba Pasia;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára.