2 Chronicles 36:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí ohun tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, pé, “Ilẹ̀ náà yóo di ahoro fún aadọrin ọdún kí ó lè ní gbogbo ìsinmi tí ó yẹ kí ó ti ní, ṣugbọn tí kò ní.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ OLÚWA tí a sọ láti ẹnu Jeremíà.