2 Chronicles 36:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, OLUWA mú ohun tí ó ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya ṣẹ. OLUWA fi sí Kirusi lọ́kàn, ó sì pàṣẹ jákèjádò ìjọba rẹ̀. Ó kọ àṣẹ náà sílẹ̀ báyìí pé:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kín-ín-ní Kírúsì ọba Pásíà, kí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí a tẹnu Jeremáyà sọ báà le ṣẹ pé, OLÚWA run ẹ̀mí Kírúsì ọba Pásíà láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọọ́ sínú ìwé pẹ̀lú.