2 Chronicles 36:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Èmi Kirusi, ọba Pasia, ni mo pàṣẹ yìí pé, ‘OLUWA Ọlọrun ọ̀run ni ó fún mi ní ìjọba lórí gbogbo ayé, òun ni ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. Nítorí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ tirẹ̀ lára yín, kí wọ́n lọ sibẹ, kí OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí Kérúsì ọba Pásíà sọ wí pé: “ ‘OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé OLÚWA fún òun ní Jérúsálẹ́mù ti Júdà. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”