2 Chronicles 36:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba Ijipti ni ó lé e kúrò lórí oyè ní Jerusalẹmu, ó sì mú àwọn ọmọ Juda ní ipá láti máa san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Éjíbítì lé e kúrò lórí ìtẹ́ ní Jérúsálẹ́mù ó sì bù fún un lórí Júdà, ọgọ́rún talẹ́ńtì fàdákà (100) àti talẹ́ntì wúrà kan.