2 Chronicles 4:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati alumagaji fitila, ati awo-koto, ati ṣibi ati awo-koto turari, wura daradara ni: ati ọ̀na iwọle, awẹ ilẹkun rẹ̀ ti inu lọhun fun ibi-mimọ́-jùlọ, ati awọn ilẹkun fun ile na, ani tempili, wura ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú àlùmágàjí fìtílà, àti àwo-kòtò àti ṣíbí àti àwo-kòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹ́ḿpìlì: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn àbáwọ inú gbọ̀ngàn ńlá.