2 Chronicles 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O ṣe agbada mẹwa pẹlu, o si fi marun si apa ọtún, ati marun si apa òsi, lati wẹ̀ ninu wọn: iru nkan ti nwọn fi nrubọ sisun ni nwọn nwẹ̀ ninu wọn; ṣugbọn agbada na ni fun awọn alufa lati ma wẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ṣe pọnunpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúṣù àti márùn ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ọrẹ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo òkun fún fífọ nǹkan.