2 Chronicles 5:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Solomoni ọba parí gbogbo iṣẹ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sinu ilé Ọlọrun: àwọn nǹkan bíi fadaka, wúrà, ati gbogbo ohun èlò, ó pa wọ́n mọ́ ninu àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n wà níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BAYI ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ṣe fun ile Oluwa pari: Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá sinu rẹ̀; ati fadakà, ati wura, ati gbogbo ohun-elo, li o fi sinu iṣura ile Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ti ṣe fún tẹ́ḿpìlì ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dáfìdì baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀sọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìsúra ilé Ọlọ́run.