2 Chronicles 5:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awon ọmọ Lefi pẹlu ti iṣe akọrin, gbogbo wọn ti Asafu, ti Hemani, ti Jedutuni, pẹlu awọn ọmọ wọn ati awọn arakunrin wọn, nwọn wọ ọ̀gbọ funfun, nwọn ni kimbali, ati ohun-elo orin, ati duru, nwọn si duro ni igun ila-õrun pẹpẹ na, ati pẹlu wọn, ìwọn ọgọfa alufa ti nwọn nfún ipè:)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kọrin: Ásáfù, Hémánì, Jédútúnì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ túntún wọ́n ń lo ohun èlò orin kínnbálì, hápù àti líà. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfaà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn.