2 Chronicles 5:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé: “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.” Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe bi ẹnipe ẹnikan, nigbati a gbọ́ ohùn awọn afunpè ati awọn akọrin, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun Oluwa; nigbati nwọn si gbé ohùn wọn soke pẹlu ipè ati kimbali, ati ohun-elo orin, lati ma yìn Oluwa pe, O ṣeun; ãnu rẹ̀ si duro lailai: nigbana ni ile na kún fun awọsanmọ, ani ile Oluwa;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn afọ̀npè àti àwọn ọ̀kọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan soso, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun OLÚWA. Wọ́n fi ìpè, kíḿbálì àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sokè láti fi yin OLÚWA, wọ́n ń kọrin pé: “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.” Nígbà náà ni ìkùku ojú ọ̀run kún inú tẹ́ḿpìlì OLÚWA,