2 Chronicles 5:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Solomoni pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, àwọn olórí ẹ̀yà, ati àwọn baálé baálé ní ìdílé Israẹli ati ti Jerusalẹmu, láti gbé àpótí majẹmu OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu tẹmpili.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Solomoni pe awọn àgbagba Israeli jọ, ati gbogbo olori awọn baba awọn ọmọ Israeli si Jerusalemu, lati mu apoti-ẹri majẹmu Oluwa gòke lati ilu Dafidi wá, ti iṣe Sioni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ sí Jérúsálẹ́mù, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Májẹ̀mu OLÚWA gòkè wá láti síónì ìlú Dáfídì.