2 Chronicles 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ọba ati gbogbo ìjọ Israẹli dúró níwájú àpótí majẹmu, wọ́n ń fi ọpọlọpọ aguntan ati ọpọlọpọ mààlúù tí kò níye rúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀, wà niwaju apoti-ẹrí na, nwọn si fi agutan ati malu rubọ, ti a kò le kà, bẹ̃ni a kò le mọ̀ iye wọn fun ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.