2 Chronicles 5:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni awọn kerubu nà iyẹ wọn bò ibi apoti-ẹri na, awọn kerubu si bò apoti-ẹri na, ati awọn ọpa rẹ̀ lati òke wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró.