2 Chronicles 5:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọpa rẹ̀ wọnni si gùn tobẹ̃, ti a fi ri ori awọn ọpa na lati ibi apoti-ẹri na niwaju ibi mimọ́-jùlọ na, ṣugbọn a kò ri wọn li ode. Nibẹ li o si wà titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí ori àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú ibi mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí.