2 Chronicles 6:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárin àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Isírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ọ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run.