2 Chronicles 6:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ li ọrun tabi li aiye: ti npa majẹmu mọ́, ati ãnu fun awọn iranṣẹ rẹ, ti nfi tọkàntọkan wọn rìn niwaju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé: “OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ.