2 Chronicles 6:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi baba mi, pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́; ti iwọ si ti fi ẹnu rẹ sọ, ti iwọ si ti fi ọwọ rẹ mu u ṣẹ, bi o ti ri loni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí.