2 Chronicles 6:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ojú rẹ kí ó lè sí sí ilé OLÚWA ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí.