2 Chronicles 6:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni sisan a fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ pada sori on tikararẹ̀; ati ni didare fun olododo, lati fifun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkárarẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún-un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.