2 Chronicles 6:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́sẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú,